Oriki Iwo

Oriki Iwo


Continuing with our Oriki Series, today we bring you Oriki Iwo. This eulogy to the Iwo people like many in our Oriki series is brought courtesy of Mr Segun Alabi.

Oriki Iwo
Iwo olodo oba, omo ateni gbola, teni gbore nile odidere
Omo oba to lu gberin afiporo je omo to lu gberin gberin
Iwo ti ko nilekun beni koni kokoro, Eru wewe ni won fi n dele
Eru ko gbodo je m’ogberin, Iwofa ko gbodo je mogbede
Omo bibi inun won ni je m’oderin
Bi wo kola biwo kolowo lowo, eru ti n se mi ni rami ta mi to mi ni temi o jare
Iwo lomo Olola ti n san keke, Iwo lomo oloola ti n bu abaja
Agbere ni wa won ki gbowo Ila lowo awa
Eyin lomo ara eru ke omo, omo ara eru bere eni
Omo araya le ki omo tode. Iwo ilu Alfa
Iwo todidere pepepe tenure te k’oroyin.
Edumare Bawa Da Ilu Iwo Si
Amin, Ase