Oriki Awori

Oriki Awori

Haven established the meaning and importance of Oriki to the Yoruba people, we hope to bring you Oriki of some of the popular Yoruba tribes. The Oriki will be both in text, audio and video format. We are starting with text format. In this text, we bring you Oriki Awori, courtesy of Ogbeni Sugun Alabi.  You can read the oriki Iwo here.

Oriki Awori….
Mariwo eh eh, agan eh eh
Mariwo tu yeri yeri
Agan tu yeri yeri
Awori Omo Akesan, omo oloko ni ilu Isheri,
Omo iwaju oloko to n s’owo,
Eyinkule oloko to nso ejigba’leke,
Omo ogedengede oloko to ntan yebe yebe loju omi,
Omo kafopa wa kafaje wa, ka tun sopa nu ka s’aje nu,
Kafogede gede owo w’ako de’le Isheri,
Omo agbeleke r’eru, omo eyigba, omo onitigbo mokun,
Omo erin gbokun yin ibon ode, omo ere fa kalu,
Omo oro nje omo oro nso, omo abi maku omo are maso,
Omo okansoso ajanaku to n migbo kijikiji…..
Omo Ogunrombi, omo arogun masa, omo ogun
niwase.
Edumare Jowo Bawa Da Ilu Awori Si

Ase